Luke 23:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Hẹrọdu rí Jesu, inú rẹ̀ dùn pupọ. Nítorí ó ti pẹ́ tí ó ti fẹ́ rí i, nítorí ìró rẹ̀ tí ó ti ń gbọ́. Ó ń retí pé kí Jesu ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Herodu si ri Jesu, o yọ̀ gidigidi: nitoriti o ti nfẹ ẹ ri pẹ́, o sa ti ngbọ́ ìhin pipọ nitori rẹ̀; o si tanmọ̃ ati ri ki iṣẹ iyanu diẹ ki o ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Hẹ́rọ́dù, sì rí Jésù, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ ó sáà ti ń gbọ́ ìhìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.