Luke 24:44 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá sọ fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ tí mo sọ fun yín nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìyí, pé dandan ni kí ohun gbogbo tí a sọ nípa mi kí ó ṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ wọ́n sílẹ̀ ninu ìwé Òfin Mose ati ninu ìwé àwọn wolii ati ninu ìwé Orin Dafidi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mósè, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Sáàmù, nípasẹ̀ mi.”