Luke 24:49 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo rán ẹ̀bùn tí Baba mi ṣe ìlérí sí orí yín. Ṣugbọn ẹ dúró ninu ìlú yìí títí agbára láti òkè wá yóo fi sọ̀kalẹ̀ sórí yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalemu, titi a o fi fi agbara wọ̀ nyin, lati oke ọrun wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì kíyèsí i, mo rán ìlérí Baba mi sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerúsálémù, títí a ó fifi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”