Luke 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Johanu sọ fún gbogbo eniyan pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín, ṣugbọn ẹni tí ó jù mí lọ ń bọ̀. Èmi kò tó ẹni tíí tú okùn bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni yóo fi wẹ̀ yín mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jòhánù dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamtíìsì yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ńbọ̀, okùn bàtà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ítú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamtísì yín: