Luke 4:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnu ya gbogbo eniyan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni èyí? Nítorí pẹlu àṣẹ ati agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì ń jáde!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hà si ṣe gbogbo wọn nwọn si mba ara wọn sọ, wipe, Ọ̀rọ kili eyi! nitori pẹlu aṣẹ ati agbara li o fi ba awọn ẹmi aimọ́ wi, nwọn si jade kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “ẹ̀kọ́ kínni èyi? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.”