Luke 5:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnu ya Jakọbu náà ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Simoni. Jesu wá sọ fún Peteru pé, “Má bẹ̀rù. Láti ìgbà yìí lọ eniyan ni ìwọ yóo máa mú wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ ni Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede, ti nṣe olupẹja pọ pẹlu Simoni. Jesu si wi fun Simoni pe, Má bẹ̀ru; lati isisiyi lọ iwọ o ma mú enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Jákọ́bù àti Jòhánù àwọn ọmọ Sébédè, tí ń ṣe alábàákẹ́gbẹ́ Símónì. Jésù sì wí fún Símónì pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa sàwárí àwọn ẹlẹ́sẹ̀.”