Luke 5:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn Farisi ati àwọn amòfin jókòó níbẹ̀. Wọ́n wá láti gbogbo ìletò Galili ati ti Judia ati láti Jerusalẹmu. Agbára Oluwa wà pẹlu Jesu láti fi ṣe ìwòsàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ni ijọ kan, bi o si ti nkọ́ni, awọn Farisi ati awọn amofin joko ni ìha ibẹ̀, awọn ti o ti ilu Galili gbogbo, ati Judea, ati Jerusalemu wá: agbara Oluwa si mbẹ lati mu wọn larada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ijọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Gálílì gbogbo, àti Jùdíà, àti Jerúsálémù wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.