Luke 5:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lefi bá se àsè ńlá fún Jesu ninu ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ẹlòmíràn, tí wọn ń bá wọn jẹun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lefi si se àse nla fun u ni ile rẹ̀: ọ̀pọ ijọ awọn agbowode, ati awọn ẹlomiran mbẹ nibẹ̀ ti nwọn ba wọn joko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Léfì sì ṣe àṣè ńlá kan fún Jésù ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn.