Luke 5:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn akọwe, ati awọn Farisi nkùn si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti ẹ mba wọn mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn Farisí, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn “èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ́lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”