Luke 6:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si da wọn li ohùn, wipe, Ẹnyin kò kawe to bi eyi, bi Dafidi ti ṣe, nigbati ebi npa on tikararẹ̀ ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkárarẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀;