Luke 6:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹ̀yin bá wín fún ẹni tí ẹ̀yin ń reti láti rí gbà padà, ọpẹ́ kínni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́sẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́sẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà.