Luke 6:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu wá tún pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Afọ́jú kò lè fi ọ̀nà han afọ́jú. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú kòtò ni àwọn mejeeji yóo bá ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si pa owe kan fun wọn, Afọju le ṣe amọ̀na afọju? awọn mejeji kì yio ṣubu sinu ihò?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì pa òwe kan fún wọn: “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí?