Luke 6:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Ọ̀rẹ́, jẹ́ kí n bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí o kò rí ìtì igi tí ó wà lójú ara rẹ? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi kúrò lójú ara rẹ, nígbà náà, ìwọ óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi iwọ o ti ṣe le wi fun arakunrin rẹ pe, Arakunrin, jẹ ki emi ki o yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, nigbati iwọ tikararẹ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? iwọ agabagebe, tètekọ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi kuro ti mbẹ li oju arakunrin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ èérún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkararẹ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.