Luke 6:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé, tí ó wa ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí ó jìn, tí ó wá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé orí àpáta. Nígbà tí ìkún omi dé, tí àgbàrá bì lu ilé náà, kò lè mì ín, nítorí wọ́n kọ́ ọ dáradára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O jọ ọkunrin kan ti o kọ́ ile, ti o si walẹ jìn, ti o si fi ipilẹ sọlẹ lori apata: nigbati kíkun omi de, igbi-omi bilù ile na, kò si le mì i: nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori apata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi bì lu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.