Luke 6:49 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò ṣe é, ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé kalẹ̀ láì ní ìpìlẹ̀. Nígbà tí àgbàrá bì lù ú, lẹsẹkẹsẹ ni ó wó, ó sì wó kanlẹ̀ patapata.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹniti o gbọ́, ti kò si ṣe, o dabi ọkunrin ti o kọ́ ile si ori ilẹ laini ipilẹ; nigbati igbi-omi bilù u, lọgan o si wó; iwó ile na si pọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì se é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi bì lù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”