Luke 7:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ ẹnu odi ìlú náà, wọ́n rí òkú ọmọ kan tí wọn ń gbé jáde. Ọmọ yìí nìkan náà ni ìyá rẹ̀ bí. Opó sì ni ìyá náà. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti inú ìlú wá pẹlu obinrin náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ti sunmọ ẹnu bode ilu na, si kiyesi i, nwọn ngbé okú kan jade, ọmọ kanṣoṣo na ti iya rẹ̀, o si jẹ opó: ọ̀pọ ijọ enia ilu na si wà pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsí i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.