Luke 7:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n jọ àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà. Àwọn kan ń pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé, ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, A sun rárà òkú fun yín, ẹ kò sunkún.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn dabi awọn ọmọ kekere ti o joko ni ibi ọjà, ti nwọn si nkọ si ara wọn, ti nwọn si nwipe, Awa fùn fère fun nyin, ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé “ ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín, ẹ̀yin kò sọkún!’