Luke 8:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí ó bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà ni àwọn tí wọ́n gbọ́, lẹ́yìn náà èṣù wá, ó mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má baà gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni Èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.