Luke 8:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obinrin kan tí Jesu ti wòsàn kúrò ninu ẹ̀mí èṣù ati àìlera ń bá a kiri. Ninu wọn ni Maria tí à ń pè ní Magidaleni wà, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje jáde ninu rẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Màríà tí a ń pè ní Magidalénè, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò.