Luke 8:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ni wọ́n bá lọ jí Jesu, wọ́n ní, “Ọ̀gá! Ọ̀gá! Ọkọ̀ mà ń rì lọ!” Ni Jesu bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi wí, ni ìgbì bá rọlẹ̀, gbogbo nǹkan bá dákẹ́ jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si da, idakẹ-rọrọ si de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò sègbé!” Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé.