Luke 8:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó ti bọ́ sí èbúté, ọkunrin kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú ìlú wá pàdé rẹ̀. Ó ti pẹ́ tí ó ti fi aṣọ kanra gbẹ̀yìn, kò sì lè gbé inú ilé mọ́, àfi ní itẹ́ òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì.