Luke 8:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Jesu ti pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò ninu ọkunrin yìí. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ní í máa ń dé sí i. Wọn á fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́, wọn á tún kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Ṣugbọn jíjá ni yóo já ohun tí wọ́n fi dè é, ni yóo bá sálọ sinu aṣálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
(Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkúgbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì dá gbogbo ìdè náà, ẹmi ẹ̀sù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù).