Luke 8:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá jáde kúrò ninu ọkunrin tí à ń wí yìí, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, ni agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí inú òkun, wọ́n bá rì sómi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ẹ̀mí ẹ̀sù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ: agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.