Luke 9:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sọ fún un pé, “Tú àwọn eniyan wọnyi ká kí wọ́n lè lọ sí àwọn abúlé káàkiri ati àwọn ìletò láti wọ̀ sí ati láti wá oúnjẹ, nítorí aṣálẹ̀ ni ibi tí a wà yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọjọ bẹ̀rẹ si irẹlẹ, awọn mejila wá, nwọn si wi fun u pe, Tú ijọ enia ká, ki nwọn ki o le lọ si iletò ati si ilu yiká, ki nwọn ki o le wọ̀, ati ki nwọn ki o le wá onjẹ: nibi ijù li awa sá gbé wà nihinyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rẹlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: níbi ijù ni àwa sá wà níhín-ín.”