Luke 9:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Wọ́n dáhùn pé, “A kò ní oúnjẹ pupọ, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji, ṣé kí àwa fúnra wa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn eniyan wọnyi ni?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Ẹ fi onjẹ fun wọn jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun lọ, pẹlu ẹja meji; bikoṣepe awa lọ irà onjẹ fun gbogbo awọn enia wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!” Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-un lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.”