Luke 9:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo sọ fun yín dájúdájú, àwọn mìíràn wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi wi fun nyin nitõtọ, ẹlomiran duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri ijọba Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìnín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”