Luke 9:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí àwọn meji yìí ti ń kúrò lọ́dọ̀ Jesu, Peteru sọ fún un pé, “Ọ̀gá, ìbá dára tí a bá lè máa wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pa àgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, ati ọ̀kan fún Elija.” Ó sọ èyí nítorí kò mọ ohun tíì bá sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati nwọn lọ kuro lọdọ rẹ̀, Peteru wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa ki a mã gbé ihinyi: jẹ ki awa ki o pa agọ́ mẹta; ọkan fun iwọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah: kò mọ̀ eyi ti o nwi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Pétérù wí fún Jésù pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí: jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta; ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)