Luke 9:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba gbà ọmọde yi nitori orukọ mi, o gbà mi: ati ẹnikẹni ti o ba gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi: nitori ẹniti o ba kere ju ninu gbogbo nyin, on na ni yio pọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí: àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi: nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀.”