Malachi 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, jákèjádò gbogbo ayé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ ni orúkọ mi ti tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ibi gbogbo ni wọ́n sì ti ń sun turari sí mi, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ mímọ́ sí mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori lati ilã-õrùn titi o si fi de iwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yio tobi lãrin awọn keferi; nibi gbogbo li a o si fi turàri jona si orukọ mi, pẹlu ọrẹ mimọ́: nitori orukọ mi o tobi lãrin awọn keferi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Orúkọ mi yóò tóbi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀ oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ ọ̀ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.