Malachi 1:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀ ń sọ pé, “Èyí sú wa!” Ẹ̀ ń yínmú sí mi. Ẹran tí ẹ fi ipá gbà, tabi èyí tí ó yarọ, tabi èyí tí ń ṣàìsàn ni ẹ̀ ń mú wá láti fi rúbọ. Ṣé ẹ rò pé n óo gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yín?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin wi pẹlu pe, Wo o agara kili eyi! ẹnyin ṣitìmú si i, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; ẹnyin si mu eyi ti o ya, ati arọ, ati olokunrùn wá; bayi li ẹnyin mu ọrẹ wá: emi o ha gbà eyi lọwọ nyin? li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó farapa, arọ àti olókùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rúbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni OLÚWA wí.