Malachi 1:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ègún ni fún arẹ́nijẹ; tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ akọ ẹran láti inú agbo rẹ̀, ṣugbọn tí ó fi ẹran tí ó ní àbùkù rúbọ sí OLUWA. Ọba ńlá ni mí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ifibu ni fun ẹlẹtàn na, ti o ni akọ ninu ọwọ́-ẹran rẹ̀, ti o si ṣe ileri ti o si fi ohun abùku rubọ si Oluwa; nitori Ọba nla li emi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ẹ̀ru si li orukọ mi lãrin awọn keferi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹ̀ran tó lábùkù rúbọ sí OLÚWA; nítorí Ọba ńlá ni Èmi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.