Malachi 1:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Edomu bá sọ pé, “Ìlú wa ti di òkítì àlàpà, ṣugbọn a óo tún un kọ́.” Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo wá dáhùn pé, “Wọ́n lè máa kọ́ ọ, ṣugbọn n óo tún máa wó o lulẹ̀ títí tí àwọn eniyan yóo fi máa pè wọ́n ní orílẹ̀-èdè burúkú, àwọn ẹni tí OLUWA bínú sí títí lae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Edomu wipe, A run wa tan, ṣugbọn awa o padà, a si kọ ibùgbe ahoro wọnni; bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Nwọn o kọ, ṣugbọn emi o wo lulẹ; Nwọn o si pe wọn ni, Agbègbe ìwa buburu, ati awọn enia ti Oluwa ni ikọnnu si titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Édómù lè wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́.” Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí pé: “Àwọ́n lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀. Wọn yóò sì pè wọ́n ní Ilẹ̀ Búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú OLÚWA.