Malachi 1:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọla mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀ru mi ha da? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin: Ẹnyin alufa, ti ngàn orukọ mi. Ẹnyin si wipe, Ninu kini awa fi kẹ́gàn orukọ rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ-ọ̀dọ̀ a sì máa bọlá fún ọ̀gá rẹ̀. Bí èmí bá jẹ́ baba ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí mi dà? Bí èmi bá sì jẹ́ ọ̀gá ọlá, tí ó tọ́ sí mi dà?” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ ọ̀ mi. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ ọ̀ rẹ?’