Malachi 1:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá mú ẹran tí ó fọ́jú, tabi ẹran tí ó múkùn-ún, tabi ẹran tí ń ṣàìsàn wá rúbọ sí mi, ǹjẹ́ kò burú? Ṣé ẹ lè fún gomina ní irú rẹ̀ kí inú rẹ̀ dùn si yín, tabi kí ẹ rí ojurere rẹ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnyin ba si fi eyi ti oju rẹ̀ fọ́ rubọ, ibi kọ́ eyini? bi ẹnyin ba si fi amúkun ati olokunrùn rubọ, ibi kọ́ eyini? mu u tọ bãlẹ rẹ lọ nisisiyi; inu rẹ̀ yio ha dùn si ọ, tabi yio ha kà ọ si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé ìyẹn kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúkùnún àti aláìsàn ẹran rúbọ, ṣé ìyẹn kò ha bògìrì bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rúbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.