Malachi 2:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣebí baba kan náà ló bí wa? Ṣebí Ọlọrun kan náà ló dá wa? Kí ló dé tí a fi ń ṣe aiṣootọ sí ara wa, tí a sì ń sọ majẹmu àwọn baba wa di aláìmọ́?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Baba kanna ki gbogbo wa ha ni? Ọlọrun kanna kó ha da wa bi? nitori kili awa ha ṣe nhùwa arekerekè olukuluku si arakunrin rẹ̀, nipa sisọ majẹmu awọn baba wa di alaimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní? Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí? Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhùwà àrékérekè olúkulùkù sí arákùnrin rẹ̀?