Malachi 2:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Juda jẹ́ alaiṣootọ sí OLUWA, àwọn eniyan ti ṣe ohun ìríra ní Israẹli ati ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Juda ti sọ ibi mímọ́ tí OLUWA fẹ́ràn di aláìmọ́; àwọn ọmọkunrin wọn sì ti fẹ́ àjèjì obinrin, ní ìdílé abọ̀rìṣà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Juda ti nhùwa arekerekè, a si ti nhùwa irira ni Israeli ati ni Jerusalemu: nitori Juda ti sọ ìwa mimọ́ Oluwa di alaimọ́, eyi ti o fẹ, o si ti gbe ọmọbinrin ọlọrun ajeji ni iyàwo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Júdà ti ń hùwà àrékérekè, a sì ti hùwà ìríra ní Ísírẹ́lì àti ni Jérúsálẹ́mù: nítorí Júdà tí ṣe eyi ti ó lè sọ ibi mímọ́ OLÚWA di aláìmọ́ nípa gbígbé ọmọbìnrin ọlọ́run àjèjì ni ìyàwó.