Malachi 2:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí OLUWA yọ irú eniyan bẹ́ẹ̀ kúrò ní àwùjọ Jakọbu, kí ó má lè jẹ́rìí tabi kí ó dáhùn sí ohun tíí ṣe ti OLUWA, kí ó má sì lọ́wọ́ ninu ẹbọ rírú sí OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ lae!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio ke ọkunrin na ti o ṣe eyi kuro, olukọ ati ẹniti a nkọ, kuro ninu agọ Jakobu wọnni, ati ẹniti nrubọ ọrẹ si Oluwa awọn ọmọ-ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ti ẹni tí ó se èyí, ẹni tí ó wù kí ó jẹ, kí OLÚWA kí ó gé e kúrò nínú àgọ́ Jákọ́bù, bí ó tilẹ̀ mú ẹbọ ọrẹ wá fún OLÚWA àwọn ọmọ ogun.