Malachi 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí kò fi gbà á?” Ìdí rẹ̀ ni pé, OLUWA ni ẹlẹ́rìí majẹmu tí ẹ dá pẹlu aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín, tí ẹ sì ṣe aiṣootọ sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrànlọ́wọ́ yín ni, òun sì ni aya tí ẹ bá dá majẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹnyin wipe, Nitori kini? Nitori Oluwa ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati lãrin aya ewe rẹ, ẹniti iwọ ti nhùwa ẹ̀tan si: bẹ̃li ẹgbẹ́ rẹ li on sa iṣe, ati aya majẹmu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí OLÚWA ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti láàrin aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn síi: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkeji rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ.