Malachi 2:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On kò ha ti ṣe ọkan? bẹ̃li on ni iyokù ẹmi. Ẽ si ti ṣe jẹ ọkan? ki on ba le wá iru-ọmọ bi ti Ọlọrun. Nitorina ẹ tọju ẹmi nyin, ẹ má si jẹ ki ẹnikẹni hùwa ẹ̀tan si aya ewe rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run kò hà ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín l'ọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín;