Malachi 2:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli wipe, on korira ikọ̀silẹ: ẹnikan fi ìwa-ipá bò aṣọ rẹ̀ mọlẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ ẹmi nyin, ki ẹ má ṣe hùwa ẹ̀tan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,” ni OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ni OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “bẹ́ẹ̀ ni mo kóríra kí èníyàn máa fi ipá bó ara rẹ̀ àti pẹ̀lú asọ rẹ̀,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí. Nítorí náà ẹ sọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má se hùwà ẹ̀tàn.