Malachi 2:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ yín ti sú Ọlọrun, sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, “Báwo ni a ṣe mú kí ọ̀rọ̀ wa sú u?” Nítorí ẹ̀ ń sọ pé, “Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe burúkú jẹ́ eniyan rere níwájú OLUWA, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn.” Tabi nípa bíbèèrè pé, “Níbo ni Ọlọrun onídàájọ́ òdodo wà?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin ti fi ọ̀rọ nyin dá Oluwa li agara. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kini awa fi da a lagara? Nigbati ẹnyin wipe, Olukulùku ẹniti o ṣe ibi, rere ni niwaju Oluwa, inu rẹ̀ si dùn si wọn; tabi, nibo ni Ọlọrun idajọ gbe wà?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ti fi ọ̀rọ̀ yin dá OLÚWA ní agara. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèré pé, “Nínú kín ni àwa fi dá a lágara?” Nígbà tí ẹ̀yìn wí pé, “Gbogbo ẹni tí ó ṣe ibi, rere ni níwájú OLÚWA, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn,” tabi “Níbo ni Ọlọ́run ìdájọ́ gbé wà?”