Malachi 2:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Majẹmu ìyè ati alaafia ni majẹmu mi pẹlu Lefi. Mo bá a dá majẹmu yìí kí ó baà lè bẹ̀rù mi; ó sì bẹ̀rù mi, ó bọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Majẹmu mi ti iyè on alafia wà pẹlu rẹ̀; mo si fi wọn fun u, nitori bibẹ̀ru ti o bẹ̀ru mi, ti ẹ̀ru orukọ mi si bà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Májẹ̀mu mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mu ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀; mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á.