Malachi 2:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti ẹnu alufaa ni ó ti yẹ kí ìmọ̀ ti máa jáde, kí àwọn eniyan sì máa gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé, iranṣẹ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ète alufa iba ma pa ìmọ mọ, ki nwọn ki o si ma wá ofin li ẹnu rẹ̀: nitori onṣẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun li on iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí ètè àlùfáà ní a ti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni iransẹ OLÚWA àwọn ọmọ ogun.