Malachi 2:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn ẹ̀yin alufaa ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́, ẹ ti mú ọ̀pọ̀ eniyan kọsẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ yín, ẹ sì ti da majẹmu tí mo bá Lefi dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹnyin ti yapa kuro li ọ̀na na: ẹnyin ti mu ọ̀pọlọpọ kọsẹ ninu ofin; ẹnyin ti ba majẹmu Lefi jẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Léfì jẹ́,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.