Malachi 2:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, n óo pa yín dà sí àìdára, ẹ óo sì di yẹpẹrẹ lójú àwọn eniyan; nítorí pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ̀ ń fi ojuṣaaju bá àwọn eniyan lò nígbà tí ẹ bá ń kọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li emi pẹlu ṣe sọ nyin di ẹ̀gan, ati ẹni aikàsi niwaju gbogbo enia, niwọ̀n bi ẹnyin kò ti pa ọ̀na mi mọ, ti ẹnyin si ti nṣe ojusaju ninu ofin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúṣàájú nínú òfin.”