Malachi 3:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Wò ó! Mo rán òjíṣẹ́ mi ṣiwaju mi láti tún ọ̀nà ṣe fún mi. OLUWA tí ẹ sì ń retí yóo yọ lójijì sinu tẹmpili rẹ̀; iranṣẹ mi, tí ẹ sì tí ń retí pé kí ó wá kéde majẹmu mi, yóo wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
KIYESI i, Emi o rán onṣẹ mi, yio si tún ọ̀na ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio de li ojijì si tempili rẹ̀, ani onṣẹ majẹmu na, ti inu nyin dùn si; kiye si i, o mbọ̀ wá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ mi, yóò si tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni OLÚWA, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹ́ḿpìlì rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.