Malachi 3:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobẹ̃ ti ki yio si aye to lati gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ báà lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́ sílẹ̀ jáde fún yín, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì àyè láti gbà á.