Malachi 3:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ sọ pé, ‘Kí eniyan máa sin Ọlọrun kò jámọ́ nǹkankan. Kò sì sí èrè ninu pípa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ninu rírẹ ara wa sílẹ̀ níwájú OLUWA àwọn ọmọ ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ̀yín ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń sọ̀fọ̀ ní iwájú OLÚWA àwọn ọmọ ogun?