Malachi 3:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn, wọn yóo jẹ́ ohun ìní mi pataki. N óo ṣàánú fún wọn bí baba tií ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si jẹ temi ni ini kan, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li ọjọ na ti emi o dá; emi o si dá wọn si gẹgẹ bi enia iti ma dá ọmọ rẹ̀ si ti o nsìn i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò ń sìn ín sí.