Malachi 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn, ta ló lè farada ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá dé? Àwọn wo ni wọn yóo lè dúró ní ọjọ́ tí ó bá yọ? Nítorí pé ó dàbí iná alágbẹ̀dẹ tí ń yọ́ irin, ati bí ọṣẹ alágbàfọ̀ tí ń fọ nǹkan mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn tali o le gbà ọjọ wíwa rẹ̀? tani yio si duro nigbati o ba fi ara hàn? nitori on dabi iná ẹniti ndà fadakà, ati bi ọṣẹ afọṣọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀: